Tuesday, 10 June 2014

IDANILEKO AKOKO FUN OLUKO EKO OJO ISIMI

2014 IDANILEKO AKOKO FUN
OLUKO EKO OJO ISINMI
ORO IKINIKABO OLUSO-AGUTAN OYEBAMIJI JOHNSON
OLUDISILE ATI ADARI IDANILEKO
AKORI: PATAKI IMURASILE
-                  Gegebi bi ohun elo mimo
-                  Ti a ti mu awon gedegede kuro. 2 Timoti 2:20
-                  Pe eniti o ko bi a se nmurasile nikan ni Olorun le pe fun ise Re, ti yio si pe e ninu ise Olorun ni sise ati mimu eso toye jade ninu ise iriju re.
-                  Ati pe imura-sile ma mu idagba soke ba Oluko ninu ise re – 2 Timoti 2:16-19, 15
-                  Pe Olorun papa ran enia kan siwaju ibi Jesu lati tun ona Re se – Luku 1:76
-                  Isodotun Ojuse wa – 1 Timotu 6:20
a.     Itoju awon ohun ti a fi le wa lowo
b.    Tita kete si oro asan
c.     Ise ilaja ni Jesu gbe le wa lowo lati se larin awon enia ati Olorun – 2 Korinti. 5:19
-                  Isodotun Igbagbo
a.     Igbagbo tiwa si Olorun ati ise Olorun gbodo di otun
b.    Igbagbo awon enia si odo Olorun gbodo ma dotun ni ojojumo – Isa. 41:1; Kolosse 3:10; Psal. 51:10
c.     Mimu Ijo dagba ninu Igbagbo si Olorun – Ise 16:5-
IPE PE KI A DAGBA SOKE NINU IKONI  TI A NSE; nitori –
a.               abayori ikoni awon enia je ti aiyeraiye
b.              nitori eko wa ndari aiye awon enia ni
c.               aye wa fun Oluko lati ni idagba soke ninu ise ikoni – Jos. 1:8;
d.              Nipa nilani ebun re
e.               Idagba ninu Bibeli kika – 1 Pet. 2:2
f.                Siso otito pelu ife – Efesu 4:15
g.               Pe iwe eko Ojo isinmi nikan ko to fun wa lai lo sinu iwe mimo wa.
OWO IDIYELE FUN IDAGBA SOKE
-                  Pe Oluko gbodo setan lati san owo idiyele idagba soke
-                  Fun awon kan ati salaye oro idiyele soro die na nitori ilora won si oro Olorun
-                  Omo owo si ni won – Heb. 5:11-14
-                  Oluko gbodo setan lati ma mura sile dada fun ise ikoni
-                  IFE  lati ma dagba ninu oro Olorun se Pataki fun Oluko oro Olorun
-                  Ife pe mo fe ki awon ti mo nko ni eko oro Olorun ki o posi.
-                  Ni akoko yi, Jesu npe wa fun idigba ni ikoni – Ipe nla ni, Ipenija ni pelu – Matthew 28:18-20
-                  Kiko awon enia daradara nikakn lo le te Jesu lorun.
-                  Emi Mimo wa nibe lati ko wa, lati ran wa lowo ninu ise ikoni wa.
Ti a ba sin so nipa Ikoni
-                  o ni se pelu idapo pelu Emi Mimo (Olutumo, Olufuniloye)
-                  idapo lojojumo pelu oro Olorun kika.
Jesu yan awon mejila lfun ise yi
-                  Won la eko daradara koja ki won to di Olukoni
-                  Jesu ko won lati kun oju osuwon ti Olorun fe
-                  Eko fun Oluko ni orekore se Pataki; fun idagba ninu ise na
-                  Ako gbodo fojudi ipe fun eko.
O sesepe o le je pe oro kan pere ninu eko na ni yio su wa si waju ninu ise iriju wa.
-         E ye lati wadi ara wa gegebi Oluko
          a.       ta ni mo je lowolowo yi?
          b.       Nje mo si wa ninu igbagbo  sibe?
          c.       se iwa mi ko ma tako eko ti mo nko awon enia bi?
          d.       se ife mi si awon enia dara to
                    -         igbala okan won
                    -         ilosiwaju aiye won
                    -         igbe aiye ti Olorun nfe, ti Olorun nreti lowo enikokan
          e.       Nje aiye won nilo adura bi ni ikorita kan?
AWON IGBESE TO HAN DADA FUN IDAGBA SOKE NINU IKONI
-                  Mi mo ohun ti a ni fun lilo
-                  Jijewo ibi ti a ku si fun ise-ikoni wa
-                  Self-appraisal – bi apere
a.     iriri igbe aiye Kristeni, se mo ni?
b.    Se mo ni ailera kan bi?
c.     Se mo ni emi oyaya tabi iko-enia mora bi?
d.    Se iwa alnikan jopon wa ninu iwa bi?
e.     Eniti nse suru ni akoko isoro inu ise iranse ni mi bi?
f.      Oloye oro Olorun ni bi?
g.     Eniti ngbadura ni gbogbo igba ni mi bi?
h.    Se mo ni ife Kristi ati Ijo Re bi?
i.      Eniti o ma fe lati jeer okan awon enia ni mi bi?
AWON ENIA TI O SE ISE OLUKO DARADARA
-                  Oluko gbodo eniti o ni ebun oro Olorun fun enia ni otun – Matt. 11:25-26
-                  Oluko oro Olorun gbodo je eniti o wasu Kristi ninu eko re – Fili.3:7-12
-                  Ife Olorun si enia ati si ara wa – John 15:12, 1 John. 4:8
-                  Kika Bibeli nigbagbogbo fun awon idi wonyi:
a.     enia ko le pe laisi oro Olorun
b.    iranlowo ati orun wa
c.     Bibeli lo le mu nip e ninu ise iranse ikoni – 2 Tim. 3:15-17
d.    Bibeli ni iwe fun igba aiye mimo – Ps. 119:105; Owe 30:5; Luku 11:28
-                  Bakanna a gbodo gbiyanju lati wa ona lati mu ki awon akeko ma ka Bibeli won ni ile –
a.     nipa fi fun won ni ise se
b.    ki a je ki o ye isegun ati ibukun to wa nibe
c.     ki a ma fun awon ni aiye lati soro okan won jade, nipa bee, a ma ti ipa be mo emi ti o ngbe inu won.
ERO OTUN  - Pataki ni ero toga ni inu ise ikoni
-                  ti ko ba si ero to dara to si ga, yio ma mu ijakule ise ikoni
-                  ero to ga yio ma mu eto ologon ba ise ikoni wa.
IDAGBA FUN IMURA SILE TI O YE, TI OLORUN NRETI LODO WA
-                  Wiwa ibi ti o dara lati joko ka iwe mimo
-                  Ko gbodo je ibi ti o le mu idiwo wa
-                  Bi ti idakeroro wa, nitori osese ki Emi Mimo ni oro lati so fun wa ni akoko gbigbe iwe mimo yewo.
-                  Si se eto ohun gbogbo ti a nilo fun kika Bibeli; bi biro, joota, Bibeli, tabili, to ba sese Bibeli Atoka.
-                  Sugbon ma se pa akoko ayewo fun ikoni pelu akoko iyawo Bibeli fun idagba soke tire ninu emi Olorun.
-                  Fifa ila si abe oro Pataki ti o ba pade
-                  Akori fun iwaasu le je jade ni akoko kia Bibeli re – ma se ro pe emi ki kuku se Oniwaasu Oro Olorun.
-                  Jije eniti o ma mura sile lati wa ojuti si isoro awon enia ninu oro Olorun ninu ile iwe eko ojo isimi.
-                  Mimu awon oro ti o fe lo jade ninu ohun ti o ka ninu Bibeli re tabi iwe eko ojo isimi
-                  Wa iriri kan ti o ti ni nipa eko ti o fe fi ko awon enia
-                  Ma gbadura fun imole atoke wa sinu aiye re, sinu oro na ati sinu aiye awon akeko
-                  Igbeyewo fun imura sile fun ikoni pelu opo enia dara nitori awon idi wonyi –
a.     ero awon yoku lori eko na je ibukun
b.    ero tiwon le yato si tire
c.     ijiroro lori isoro inu eko na
d.    igbekale ma yato, iwa ri eko ko ninu re
e.     opin ijiroro na ma mu eko, iriri otun wa.
-                  Imoran mi fun yin ni pe – Ki e je ki Emi Mimo enikeji re timotimo ninu yiyewo Bibeli ati ninu ise iriju re.

-                  Mo fi yin le Emi Mimo lowo ni oruko Jesu Kristi Olugbala wa.i